Ezekiel 40:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnu ọ̀nà náà ní àwọn fèrèsé tóóró tóóró yíká, tí ó ga kan àwọn àtẹ́rígbà àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́. Bákan náà, ìloro náà ní àwọn fèrèsé yíká, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ferese tõro si mbẹ lara yará kékèké na, ati lara atẹrigba wọn ninu ẹnu-ọ̀na niha gbogbo ati pẹlu yará iloro: ferese pupọ si mbẹ niha inu gbogbo: igi ọpẹ si mbẹ lara olukuluku atẹrigbà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ni a tẹ nínú yíká; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká; Awọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé ati láti fèrèsé dé òrùlé.