Ezekiel 40:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀ rí bákan náà pẹlu àwọn ti ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn yará kékèké ibẹ̀ jẹ mẹta niha ìhin, mẹta nihà ọhun; awọn atẹrigba ibẹ ati iloro ibẹ jẹ gẹgẹ bi ìwọn ẹnu-ọ̀na ekini: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ bákan náà ni wíwọ̀n gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni fífẹ̀.