Ezekiel 40:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn fèrèsé rẹ̀, ati ìloro rẹ̀ ati àwọn àwòrán ọ̀pẹ ara rẹ̀ rí bíi àwọn ti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn. Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ sì wà ninu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fèrese wọn, ati iloro wọn, ati igi ọpẹ wọn jẹ gẹgẹ bi ìwọn ti ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun; nwọn si ba atẹgun meje gùn oke rẹ̀ lọ; awọn iloro na si mbẹ niwaju wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ojú ihò rẹ̀, àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ àti igi ọ̀pẹ tí iṣe ọ̀sọ́ rẹ̀ ni wọn kàn gẹ́gẹ́ bí tí àwọn ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìlà òòrùn. Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà òdìkejì wọn.