Ezekiel 40:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Níwájú ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ni ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú wà bí ó ti wà níwájú ẹnu ọ̀nà ti ìlà oòrùn. Ọkunrin náà wọn ibẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà kan sí ikeji, ó jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹnu-ọ̀na agbala inu ti o kọju si ẹnu-ọ̀na ti ariwa, ati ti ila-õrun; o si wọ̀n lati ẹnu-ọ̀na de ẹnu-ọ̀na, ọgọrun igbọnwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnu ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni àdojúkọ ẹnu ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà òòrùn. Ó wọ̀n láti ẹnu ọ̀nà sí àdojúkọ ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.