Ezekiel 40:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó mú mi lọ sí apá ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà kan níbẹ̀. Ó wọn àtẹ́rígbà ati ìloro rẹ̀, wọ́n sì rí bákan náà pẹlu àwọn yòókù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mu mi lọ si ọ̀na gusù, si kiye si i, ẹnu-ọ̀na kan mbẹ li ọ̀na gusù: o si wọ̀n awọn atẹrigba wọn, ati ìloro wọn gẹgẹ bi ìwọn wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ gúsù. Ó wọn àtẹ́rígbà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ bákan náà bí ti àwọn tí o kù.