Ezekiel 40:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Fèrèsé yí inú ati ìloro rẹ̀ ká, bíi àwọn fèrèsé ti àwọn ẹnu ọ̀nà yòókù. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Fèrese pupọ si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu iloro wọn yika, bi ferese wọnni: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnu ọ̀nà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ni ojú ihò tóóró yí po, gẹ́gẹ́ bí ojú ihò ti àwọn tókù. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ní fífẹ̀.