Ezekiel 40:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní àtẹ̀gùn meje, ìloro rẹ̀ wà ninu, àwòrán ọ̀pẹ sì wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Atẹ̀gun meje ni mbẹ lati bá gùn oke rẹ̀, ati awọn iloro rẹ̀ si mbẹ niwaju wọn: o si ni igi ọpẹ, ọkan nihà ìhin, ati ọkan nihà ọhún, lara awọn atẹrigbà rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ní òdì kejì wọn; Ó ní igi ọ̀pẹ tí a fi ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni ojú ìgbéró ògiri ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan.