Ezekiel 40:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ pẹlu àwọn yòókù. Fèrèsé wà lára rẹ̀ yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn yará kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese pupọ̀ si mbẹ nibẹ ati ni iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu ọ̀nà náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ní ihò ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gbogbo