Ezekiel 40:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó mú mi dé ìlú náà, mo rí ọkunrin kan tí àwọ̀ rẹ̀ dàbí idẹ. Ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà, ó mú okùn òwú ati ọ̀pá tí wọ́n fi ń wọn nǹkan lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mu mi wá sibẹ, si kiyesi i, ọkunrin kan mbẹ, ẹniti irí rẹ̀ dabi irí bàba, pẹlu okùn ọ̀gbọ li ọwọ́ rẹ̀, ati ije iwọ̀nlẹ; on si duro ni ẹnu-ọ̀na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú mi lọ síbẹ̀, mo sì rí ọkùnrin kan tí ìrírí rẹ̀ dàbí ìrí bàba; ó dúró ni ẹnu ọ̀nà pẹ̀lú okùn aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun àti ọ̀pá ìwọnlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.