Ezekiel 40:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bákan náà ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, ó sì ní fèrèsé yíká. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn yará kékèké rẹ̀, atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, ati ferese rẹ̀ yika: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn yàrá ẹ̀sọ́ rẹ̀ àwọn òpó rẹ̀ àti ìloro rẹ̀, àti fèrèsé rẹ̀ yíká: gígùn rẹ̀ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àti ìbú rẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n.