Ezekiel 40:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin yìí bá pè mí, ó ní: “ìwọ ọmọ eniyan, ya ojú rẹ, kí o máa wòran, ya etí rẹ sílẹ̀, kí o máa gbọ́; sì fi ọkàn sí gbogbo ohun tí n óo fihàn ọ́; nítorí kí n baà lè fihàn ọ́ ni a ṣe mú ọ wá síbí. Gbogbo ohun tí o bá rí ni o gbọdọ̀ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin na si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi oju rẹ wò, ki o si fi eti rẹ gbọ́, ki o si gbe ọkàn rẹ le ohun gbogbo ti emi o fi han ọ; nitori ka ba le fi wọn han ọ li a ṣe mu ọ wá ihinyi: sọ ohun gbogbo ti o ri fun ile Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, wò pẹ̀lú ojú rẹ kí o sì gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ, kí ó sì farabalẹ̀ sì gbogbo ohun tí mo máa fi hàn ọ, nítorí ìdí nìyí tí a fi mú ọ wá síhìn-ín. Sọ gbogbo ohun tí ó bá rí fún ilé Ísírẹ́lì.”