Ezekiel 40:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Tabili mẹrin kan tún wà tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ìbú rẹ̀ náà jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ó sì ga ní igbọnwọ kan (bíi ìdajì mita). Lórí rẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa ẹran ẹbọ sísun ati ti ẹbọ yòókù sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tabili mẹrin na si jẹ ti okuta gbigbẹ́ fun ọrẹ ẹbọ sisun, igbọnwọ kan on ãbọ ni gigùn, ati igbọnwọ kan on ãbọ ni ibú, ati igbọnwọ kan ni giga: lori eyiti nwọn a si ma kó ohun-elò wọn le, ti nwọn ifi pa ọrẹ ẹbọ sisun ati ẹran ẹbọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tẹ́ḿpìlì mẹ́rin tí à fi òkúta ṣe lọ́sọ̀ọ́ sì tún wà fún ẹbọ sísun, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ni gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ni gíga. Ní orí rẹ̀ ni a kó àwọn ohun èlò fún pípa, ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ìrubọ tí ó kù sí.