Ezekiel 40:46 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yàrá tí ó kọjú sí ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn alufaa tí wọn ń mójútó pẹpẹ; àwọn ni àwọn ọmọ Sadoku. Àwọn nìkan ninu ìran Lefi ni wọ́n lè súnmọ́ OLUWA láti rúbọ sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yará ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na ariwa, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ pẹpẹ na; awọn wọnyi li awọn ọmọ Sadoku ninu awọn ọmọ Lefi, ti nwọn ima sunmọ Oluwa lati ṣe iranṣẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Iyàrá ti iwájú rẹ̀ ti o wà níhà àríwá, wà fún àwọn àlúfáà, àwọn ti ń bojútó pẹpẹ náà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Sádókù nínú àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n ń súnmọ́ OLÚWA láti ṣe ìránṣẹ́ fún un.”