Ezekiel 40:48 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìloro tẹmpili, ó sì wọn àtẹ́rígbà rẹ̀. Ó jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un (mita 2½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji; ìbú ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita 7). Àwọn ògiri rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta mẹta (mita 1½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mu mi wá si iloro ile na, o si wọ̀n opo iloro na, igbọnwọ marun nihà ìhin, ati igbọnwọ marun nihà ọ̀hun: ibu ẹnu-ọ̀na na si jẹ igbọnwọ mẹta nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹta nihà ọ̀hun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú mi lọ sí àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tẹ́ḿpìlì, ó sì wọn àwọn àtẹrígbà àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà; wọ́n jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní fífẹ̀, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì rẹ̀. Fífẹ̀ àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá, ìgbéró àwọn ògiri náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní fífẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì.