Ezekiel 40:49 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òòró ìloro náà jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila (mita 5½), àtẹ̀gùn rẹ̀ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, òpó sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àtẹ́rígbà rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gigùn iloro na jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ igbọnwọ mọkànla; o si mu mi wá si atẹ̀gun ti nwọn ifi ba gokè rẹ̀: ọwọ̀n pupọ̀ si mbẹ nihà ibi atẹrigbà, ọkan nihin, ati ọkan lọhun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ méjìlá láti iwájú dé ẹ̀yìn. Láti ara àtẹ̀gùn ní a ti ń dé ibẹ̀ àwọn òpó sì wà ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àwọn àtẹ́rígbà náà.