Ezekiel 40:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ náà gùn ní ìwọ̀n ọ̀pá kan, wọ́n sì fẹ̀ ní ìwọ̀n ọ̀pá kan. Àlàfo tí ó wà láàrin àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½). Àbáwọlé ẹnu ọ̀nà ẹ̀bá ìloro tí ó kọjú sí tẹmpili jẹ́ ọ̀pá kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yará kékèké si jẹ ije kan ni gigùn, ati ije kan ni ibú; ati lãrin yará kékèké igbọnwọ marun; àtẹwọ ẹnu-ọ̀na lẹba iloro ẹnu-ọ̀na ti inu si jẹ ije kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yàrá kéékèèkéé sì jẹ ọ̀pá kan ni gígùn àti ọpá kan ní ibú, ìgbéró ògiri àárin yàrá kéékèèkéé náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn. Ìloro ẹnu ọ̀nà náà tí ó kángun sí àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà náà tó kọjú sì tẹ́ḿpìlì jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn.