Ezekiel 41:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ó wọn Tẹmpili, ó gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Àgbàlá ati ilé náà pẹlu ògiri rẹ̀ gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wọ̀n ile na, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn; ati ibi ti a yà sọtọ̀, ati ile na, pẹlu ogiri wọn, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí ní ó wá wọn ilé Ọlọ́run: Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ìta gbangba ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ilé àti ògiri rẹ̀ náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn.