Ezekiel 41:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ó wọn òòró ilé ní ìhà tí ó dojú kọ àgbàlá tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn ati àwọn ògiri rẹ̀; ẹ̀gbẹ́ kinni keji gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ni wọ́n fi bo ara ògiri ibi mímọ́ jùlọ Tẹmpili náà ati yàrá inú ati
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wọ̀n gigun ile na ti o kọju si ibiti a yà sọtọ̀ ti mbẹ lẹhin rẹ̀, ati ibujoko-oke ni ihà kan ati nihà miran, ọgọrún igbọnwọ, pẹlu tempeli inu, ati iloro agbalá na;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wá wọn gígùn ilé tí ó dojúkọ gbangba ìta ní agbègbè ilé Ọlọ́run papọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́. Ìta ibi mímọ́, inú ibi mímọ́ náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìta gbangba,