Ezekiel 41:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ìloro ti ìta yíká. Àwọn mẹtẹẹta ní fèrèsé aláṣìítì. Wọ́n fi pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo ara ògiri Tẹmpili náà yíká láti ilẹ̀ títí kan ibi fèrèsé, títí kọjá ìloro. (Wọ́n fi pákó bo àwọn fèrèsé náà).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iloro, ati ferese toro, ati ibujoko oke yika lori ile olorule mẹta wọn, ti o wà niwaju iloro na, li a fi igi tẹ́ yika, ati lati ilẹ de oke ferese, a si bò awọn ferese na;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àti pẹ̀lú àwọn ìloro ilé àti àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè yípo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, gbogbo rẹ̀ ní ìta papọ̀ mọ́ ìloro ilé ni wọ́n fi igi bò. Ilẹ̀ ògiri sókè títí dé ojú fèrèsé ni wọ́n fi igi bò pátapáta.