Ezekiel 41:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
pẹpẹ tí a fi igi ṣe wà níwájú ibi mímọ́. Gíga rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta (mita 1½), òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (bíi mita kan), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ meji. Igi ni wọ́n fi ṣe igun rẹ̀, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ati ara rẹ̀. Ọkunrin náà sọ fún mi pé: “Èyí ni tabili tí ó wà níwájú OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹpẹ igi na jẹ igbọnwọ mẹta ni giga, gigùn rẹ̀ igbọnwọ meji; ati igun rẹ̀, ati gigùn rẹ̀, ati awọn ogiri rẹ̀ jẹ ti igi: o si wi fun mi pe, Eyi ni tabili ti mbẹ niwaju Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹpẹ ìrúbọ kan tí a fi igi ṣe wà, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, àwọn igun rẹ̀, ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti ògiri rẹ́ jẹ́ igi. Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Èyí yìí ní tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní iwájú OLÚWA.”