Ezekiel 41:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn fèrèsé aláṣìítì, tí wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ sí lára, wà lára ògiri ìloro náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ferese toro ati igi ọpẹ mbẹ nihà ihin ati nihà ọhun nihà iloro, ati ni yará-iha ile na, ati ni igi ibori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ògiri ẹnu ọ̀nà ní àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú igi ọ̀pẹ tí a fín ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì wà. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà ni ìbòrí tí a fi igi ṣe.