Ezekiel 41:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ alágbèékà mẹta, ọgbọ̀n yàrá ni ó sì wà ninu àgbékà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mọ òpó sí ara ògiri Tẹmpili yíká, kí wọn baà lè gba àwọn yàrá dúró kí ó má baà jẹ́ pé ògiri Tẹmpili ni óo gbé wọn ró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn yará-ihà, ọkan lori ekeji jẹ mẹta, nigba ọgbọ̀n: nwọn si wọ̀ inu ogiri ti ile awọn yará-ihà na yika, ki nwọn ba le di ara wọn mu, nitori kò si idimú ninu ogiri ile na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ wà ni ìpele mẹ́ta, lórí ara wọn, nígbà ọgbọ̀n lórí ìkọ̀ọ̀kan. Àwọn arópòdógìri wà yípo ògiri ilé Ọlọ́run náà mú kí ògiri àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́gbẹ́ náà ní agbára, ni ọ̀nà tí àwọn ìfaratì náà kò fi wọ inú ògiri ilé Ọlọ́run náà lọ.