Ezekiel 41:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn yàrá náà ń fẹ̀ sí i láti àgbékà dé àgbékà, bí òpó tí wọ́n mọ sí ara ògiri Tẹmpili ṣe ń tóbi sí i. Àtẹ̀gùn kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Tẹmpili náà tí ó lọ sókè. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àgbékà kinni, ó gba inú ti ààrin lọ sí èyí tí ó wà lókè patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si ṣe e gborò, o si lọ yika loke awọn yará ihà: nitori ogiri ile na lọ loke-loke yi ile na ka: nitorina ibú ile na wà loke, bẹ̃ni iyará isalẹ yọ si toke lãrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ yípo tẹ́ḿpìlì ń fẹ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń lọ sí òkè sí i. Àwọn ilé tí a kọ́ yípo ilé Ọlọ́run ni a kọ́ sókè ní pele ní pele, èyí mú kí àwọn yàrá yìí máa fẹ̀ sí i bí ó ṣe ń gòkè sí i. Àtẹ̀gùn rẹ̀ gba ti àwùjọ ilé àárin lọ sókè láti ilé títí dé òkè pátapáta.