Ezekiel 42:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà wí fún mi pé, “Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ìhà àríwá ati àwọn yàrá ìhà gúsù tí wọ́n kọjú sí àgbàlá ni àwọn yàrá mímọ́. Níbẹ̀ ni àwọn alufaa tí ń rú ẹbọ sí OLUWA yóo ti máa jẹ ẹbọ mímọ́ jùlọ. Níbẹ̀ ni wọn yóo máa kó àwọn ẹbọ mímọ́ jùlọ sí; ati àwọn ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, nítorí ibẹ̀ jẹ́ ibi mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Awọn yará ariwa ati awọn yará gusu, ti o wà niwaju ibiti a yà sọtọ̀, awọn ni yará mimọ́, nibiti awọn alufa ti nsunmọ Oluwa yio ma jẹ ohun mimọ́ julọ: nibẹ̀ ni nwọn o ma gbe ohun mimọ́ julọ kà, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; nitori ibẹ̀ jẹ mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn yàrá àríwá àti àwọn yàrá gúsù, tí ó wà níwájú ibi tí a yà sọ́tọ̀ àwọn ni yàrá mímọ́, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń súnmọ́ OLÚWA yó máa jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ; níbẹ̀ ní wọn o máa gbé ohun mímọ́ jùlọ kà, àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; nítorí ibẹ̀ jẹ́ mímọ́