Ezekiel 43:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ojú ohun tí wọ́n ṣe bá tì wọ́n, ṣe àlàyé Tẹmpili náà, bí o ti rí i, ẹnu ọ̀nà àbájáde ati àbáwọlé rẹ̀. Sọ bí o ti rí i fún wọn, sì fi àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ hàn wọ́n. Kọ wọ́n sílẹ̀ lójú wọn, kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi oju gbogbo ohun ti nwọn ba ṣe ba si tì wọn, fi irí ile na hàn wọn, ati kikọ́ rẹ̀, ati ijade rẹ̀, ati iwọle rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ati gbogbo irí rẹ̀, ati gbogbo ofin rẹ̀; ki o si kọ ọ loju wọn, ki nwọn ki o lè pa gbogbo irí rẹ̀ mọ, ati gbogbo aṣẹ rẹ̀, ki nwọn si ṣe wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀.