Ezekiel 43:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ìwọ̀n pẹpẹ náà ti rí nìyí; irú ọ̀pá kan náà tí ó jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ (ìdajì mita kan) kan ni ó fi wọ̀n ọ́n. Pèpéle pẹpẹ náà yóo ga ní igbọnwọ kan, yóo fẹ̀ ní igbọnwọ kan. Etí rẹ̀ yíká fẹ̀ ní ìka kan (idamẹrin mita kan).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi si ni iwọ̀n pẹpẹ nipa igbọnwọ; Igbọnwọ jẹ igbọnwọ kan ati ibú atẹlẹwọ kan; isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ kan, ati igbati rẹ̀ ni eti rẹ̀ yika yio jẹ ika kan: eyi ni yio si jẹ ibi giga pẹpẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni fífẹ̀, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ibú àtẹ́lẹwọ́ kan: Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà: