Ezekiel 43:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ náà ní igun mẹrin, ó ga ní igbọnwọ mẹrinla (mita meje), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita meje). Etí rẹ̀ yíká jẹ́ ìdajì igbọnwọ (idamẹrin mita), pèpéle rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan yíká (ìdajì mita kan). Àtẹ̀gùn pẹpẹ náà kọjú sí apá ìlà oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ijoko ni yio jẹ igbọ̀nwọ mẹrinla ni gigun ati mẹrinla ni ibú ninu igun mẹrẹrin rẹ̀; ati eti rẹ̀ yika yio jẹ́ abọ̀ igbọnwọ; ati isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan yika; atẹgùn rẹ̀ yio si kọjusi iha ila-õrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Igun ni apá òkè náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní fífẹ̀, pẹ̀lú etí tí ó jẹ́ ìdáji ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yípo. Àtẹ̀gùn pẹpẹ ìrúbọ náà dojúkọ ìlà oòrùn.”