Ezekiel 43:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin náà wí fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Àwọn òfin pẹpẹ nìwọ̀nyí, ní ọjọ́ tí a bá gbé e kalẹ̀ láti máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ ati láti máa ta ẹ̀jẹ̀ sí i lára,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni aṣẹ pẹpẹ na li ọjọ ti nwọn o ṣe e, lati rú ọrẹ ẹbọ sisun lori rẹ̀, ati lati wọ́n ẹ̀jẹ sori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ohun tí OLÚWA wí: Ìwọ̀nyí yóò jẹ́ òfin fún ìrúbọ ẹbọ sísun àti wíwọ́n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ nígbà tí a bá mọ pẹpẹ tán: