Ezekiel 43:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ óo fi sí ara ìwo pẹpẹ ati igun mẹrẹẹrin pèpéle rẹ̀, ati ara etí rẹ̀ yíká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ pẹpẹ náà mọ́; bẹ́ẹ̀ ni ètò ìwẹ̀nùmọ́ pẹpẹ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si mu ninu ẹjẹ rẹ̀, iwọ o si fi si iwo mẹrẹrin rẹ̀, ati si igun mẹrẹrin ijoko na, ati si eti rẹ̀ yika: iwọ o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọ́, iwọ o si ṣe etùtu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ ni láti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi sórí ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà lórí pẹpẹ, àti lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ìjòkòó náà àti sí gbogbo etí rẹ̀ yípo, ìwọ yóò sì sọ pẹpẹ di mímọ́, ìwọ yóò sì ṣe ètùtù rẹ̀.