Ezekiel 43:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Tí ètò àwọn ọjọ́ wọnyi bá ti parí, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹjọ, àwọn alufaa yóo máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí pẹpẹ náà, n óo sì máa tẹ́wọ́gbà wọ́n. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọjọ wọnyi ba pe, yio si ṣe, ni ọjọ kẹjọ, ati siwaju, awọn alufa yio ṣe ọrẹ ẹbọ sisun nyin lori pẹpẹ, ati ọrẹ ẹbọ idupẹ: emi o si gbà nyin, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìparí ọjọ́ wọ̀nyí, láti ọjọ́ mẹ́jọ síwájú, àwọn àlùfáà ni yóò gbé àwọn ẹbọ sísun rẹ àti ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ. Lẹ́yìn náà, èmi yóò tẹ́wọ́gba yín ní OLÚWA Ọba wí.”