Ezekiel 43:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, ààyè ìtẹ́ mi nìyí, ati ibi ìgbẹ́sẹ̀lé mi. Níbẹ̀ ni n óo máa gbé láàrin àwọn eniyan Israẹli títí lae. Ilé Israẹli tabi àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn wọn, ati òkú àwọn ọba wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, ibi itẹ mi, ati ibi atẹlẹṣẹ mi, nibiti emi o gbe lãrin awọn ọmọ Israeli lailai, ati orukọ mimọ́ mi, ni ki ile Israeli má bajẹ mọ, awọn, tabi ọba wọn, nipa panṣaga wọn, tabi nipa okú ọba wọn ni ibi giga wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgunwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi, Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí láéláé. Ilé Ísírẹ́lì kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn Ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn Ọba wọn ní ibi gíga.