Ezekiel 43:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn kò ní tẹ́ pẹpẹ wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi mọ́, tabi kí wọn gbé òpó ìlẹ̀kùn wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi; tí ó fi jẹ́ pé ògiri kan ni yóo wà láàrin èmi pẹlu wọn. Wọ́n ti fi ìwà ìríra wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, nítorí náà ni mo ṣe fi ibinu pa wọ́n run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni titẹ́ iloro wọn nibi iloro mi, ati opó wọn nibi opó mi, ogiri si wà lãrin emi ati awọn, nwọn si ti ba orukọ mimọ́ mi jẹ nipa ohun irira wọn ti nwọn ti ṣe: mo si run wọn ni ibinu mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n ba gbé ìlóro ilé wọn kangun sí ìlóro ilé mi àti ìlẹ̀kùn wọn sì ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri nìkan ní àárin èmi pẹ̀lú wọn, wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ìwà ìríra wọn. Nígbà náà ni mo pa wọ́n run ní ìbínú mi.