Ezekiel 44:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada lẹ́yìn mi, tí wọ́n ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn nígbà tí Israẹli ṣáko lọ, yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn Lefi ti o ti lọ jina kuro lọdọ mi, ni ìṣina Israeli, ti nwọn ṣìna kuro lọdọ mi lẹhin oriṣa wọn: yio si rù aiṣedede wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Àwọn Léfì tí wọn rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sìnà, ti wọ́n sì ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi láti tọ àwọn ère wọn lẹ́yìn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀sẹ̀ wọn.