Ezekiel 44:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n lè jẹ́ iranṣẹ ninu ibi mímọ́ mi, wọ́n lè máa ṣe alákòóso àwọn ẹnu ọ̀nà tẹmpili, wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, wọ́n lè máa pa ẹran ẹbọ sísun ati ẹran ẹbọ àwọn eniyan, wọ́n lè máa ṣe iranṣẹ fún àwọn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si jẹ iranṣẹ ni ibi mimọ́ mi, oluṣọ́ ẹnu-ọ̀na ile, nwọn o si ma ṣe iranṣẹ ni ile: awọn ni yio pa ọrẹ-ẹbọ sisun ati ẹbọ fun awọn enia, nwọn o si duro niwaju wọn lati ṣe iranṣẹ fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn le sìn mi ní ibi mímọ́ mi, kí wọn ṣe ìtọ́jú àwọn ẹnu ọ̀nà ilé Ọlọ́run, kí wọn sì ṣe ìránṣẹ́ nínú rẹ̀; wọn le pa ẹbọ sísun, ki wọn sì rúbọ fún àwọn ènìyàn, kí wọn sì dúró níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.