Ezekiel 44:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé wọ́n ti jẹ́ iranṣẹ fún wọn níwájú àwọn oriṣa, wọ́n sì di ohun ìkọsẹ̀ tí ó mú ilé Israẹli dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà, mo ti búra nítorí wọn pé wọ́n gbọdọ̀ jìyà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti nwọn ṣe iranṣẹ fun wọn niwaju òriṣa wọn, nwọn si jẹ ohun ìdugbolu aiṣedede fun ile Israeli: nitorina ni mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi, nwọn o si rù aiṣedede wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Ísírẹ́lì subú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní OLÚWA Ọba sọ.