Ezekiel 44:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn kò gbọdọ̀ dé ibi pẹpẹ mi láti ṣe iṣẹ́ alufaa, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ mi ati àwọn ohun mímọ́ jùlọ; ojú yóo tì wọ́n nítorí ohun ìríra tí wọ́n ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio si sunmọ ọdọ mi, lati ṣiṣẹ alufa fun mi, tabi lati sunmọ gbogbo ohun-mimọ́ mi, ni ibi mimọ́ julọ: nwọn o si rù itijú wọn, ati ohun-irira wọn ti nwọn ti ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti se ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ ìkankan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ; wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn.