Ezekiel 44:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn àwọn alufaa ọmọ Lefi láti ìran Sadoku, tí wọn ń tọ́jú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, àwọn ni yóo máa lọ sí ibi pẹpẹ mi láti rúbọ sí mi. Àwọn ni wọn óo máa fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn alufa awọn Lefi, awọn ọmọ Sadoku, ti o pa ibi-iṣọ ibi mimọ́ mi mọ, nigbati awọn ọmọ Israeli ṣìna kuro lọdọ mi, awọn ni yio sunmọ ọdọ mi lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si duro niwaju mi lati rú ọrá ati ẹjẹ si mi, ni Oluwa Ọlọrun wi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Léfì àti àwọn ìran Sádómù tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni OLÚWA Ọba sọ.