Ezekiel 44:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n bá ti dé àwọn ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn inú, wọn yóo wọ aṣọ funfun. Wọn kò ní wọ ohunkohun tí a fi irun aguntan hun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ lẹ́nu ọ̀nà ati ninu gbọ̀ngàn inú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe pe, nigbati nwọn ba wá si ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, nwọn o wọ̀ ẹ̀wu ọ̀gbọ; irun agutan kì yio bọ́ si ara wọn, nigbati nwọn ba nṣe iranṣẹ ni ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, ati ninu ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run.