Ezekiel 44:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan ní gbọ̀ngàn ìta, wọn yóo bọ́ aṣọ tí wọ́n wọ̀ nígbà tí wọn ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sí àwọn yàrá mímọ́. Wọn yóo wọ aṣọ mìíràn kí wọn má baà sọ àwọn eniyan náà di mímọ́ nítorí ẹ̀wù wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn ba si lọ si agbalá ode, ani si agbalá ode sọdọ awọn enia, nwọn o bọ́ ẹ̀wu wọn ti wọn ifi ṣe iranṣẹ, nwọn o si fi wọn si awọn yará mimọ́, nwọn o si wọ̀ ẹ̀wu miran; nwọn kì yio si fi ẹ̀wu wọn sọ awọn enia di mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ń siṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí wọn kí ó má ba à sọ àwọn ènìyàn di mímọ́ nípasẹ̀ aṣọ wọn.