Ezekiel 44:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tabi obinrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, àfi wundia tí kò tíì mọ ọkunrin láàrin àwọn eniyan Israẹli tabi opó tí ó jẹ́ aya alufaa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio si fẹ́ opo, tabi ẹniti a tì jade fun aya wọn: ṣugbọn nwọn o fẹ́ wundia lati iru-ọmọ ile Israeli, tabi opo ti o ti ni alufa ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn ko gbọdọ̀ fẹ́ opó ni ìyàwó, wọn kò sì gbọdọ̀ kọ ìyàwó wọn sílẹ̀; Wọ́n lè fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ti kò tí i mọ ọkùnrin rí, tí ó sì jẹ́ ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tàbí kí wọn fẹ́ àwọn opó Àlùfáà.