Ezekiel 44:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Wọ́n gbọdọ̀ kọ́ àwọn eniyan mi láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn nǹkan mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ ati àwọn nǹkan lásán. Wọ́n sì gbọdọ̀ kọ́ wọn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan tí kò mọ́ ati àwọn nǹkan mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si kọ́ awọn enia mi ni iyàtọ ti o wà lãrin mimọ́ ati ailọ̀wọ, nwọn o si mu wọn mọ̀ eyiti o wà lãrin aimọ́ ati mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn ní láti fi ìyàtọ̀ tí ó wà nínú mímọ́ àti aláìmọ́ kọ́ àwọn ènìyàn mi, kí wọn sì fi bi wọn yóò ṣe dá aláìmọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí mímọ́ hàn wọ́n.