Ezekiel 44:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí àríyànjiyàn bá bẹ́ sílẹ̀, àwọn ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onídàájọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí èmi gan-an yóo ti ṣe é. Wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn òfin ati ìlànà mi mọ́ lákòókò gbogbo àṣàyàn àjọ̀dún wọn, wọ́n sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ni ija, awọn ni yio duro lati ṣe idajọ; nwọn o si dá a ni idajọ mi: nwọn o si pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́ ni gbogbo apejọ mi; nwọn o si yà awọn ọjọ isimi mi si mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nínú èyíkéyi èdè-àìyedè, àwọn Àlùfáà ní ó gbọdọ̀ dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi. Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ fún gbogbo àṣẹ, wọn sì gbọdọ̀ lo ọjọ ìsinmi mi ní mímọ́.