Ezekiel 44:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Wọn kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di aláìmọ́ nípa sísúnmọ́ òkú, ṣugbọn wọ́n lè sọ ara wọn di aláìmọ́ bí ó bá jẹ́ pé òkú náà jẹ́ ti baba wọn tabi ìyá wọn tabi ti ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin tabi ti arakunrin wọn tí kò tíì gbeyawo tabi arabinrin wọn tí kò tíì wọ ilé ọkọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio si wá sọdọ okú enia lati sọ ara wọn di aimọ́, ṣugbọn fun baba, tabi fun iya, tabi fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, fun arakunrin, tabi fun arabinrin ti kò ti ni ọkọ, nwọn le sọ ara wọn di aimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa sísún mọ́ òkú ènìyàn; ṣùgbọ́n ti òkú ènìyàn yẹn bá jẹ́ bàbá tàbí ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin ti kò i ti lọ́kọ, nígbà náà o le sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.