Ezekiel 44:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àkọ́so oniruuru èso ati oniruuru ọrẹ gbọdọ̀ jẹ́ ti àwọn alufaa. Ẹ sì gbọdọ̀ fún àwọn alufaa mi ní àkọ́pò ìyẹ̀fun yín kí ibukun lè wà ninu ilé yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ikini ninu gbogbo akọ́so nkan gbogbo, olukuluku ọrẹ gbogbo, ninu gbogbo ọrẹ nyin, yio jẹ ti awọn alufa: ẹ o si fi akọ́po iyẹfun nyin fun alufa, ki ibukun le bà le ile rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ti ẹ̀bùn pàtàkì yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà. Ẹ ní láti fún wọn ní ìpín àkọ́kọ́ nínú èso ilẹ̀ yìí kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yìí.