Ezekiel 44:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá sọ fún mi pé: “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe akiyesi dáradára, ya ojú rẹ, kí o sì fi etí sílẹ̀ kí o gbọ́ gbogbo ohun tí n óo sọ fún ọ nípa àṣẹ ati àwọn òfin tí ó jẹ mọ́ tẹmpili OLUWA. Ṣe akiyesi àwọn eniyan tí a lè gbà láàyè kí wọ́n wọ inú tẹmpili ati àwọn tí kò gbọdọ̀ wọlé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi iyè rẹ si i, si fi oju rẹ wò, si fi eti rẹ gbọ́ ohun gbogbo ti emi ti sọ fun ọ niti gbogbo aṣẹ ile Oluwa, ati ti gbogbo ofin rẹ̀; si fi iyè rẹ si iwọ̀nu ile nì, pẹlu gbogbo ijadelọ ibi-mimọ́ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì sọ fún mì pé, “Ọmọ ènìyàn, wò dáadáa, fetí sílẹ̀ dáadáa kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa ofin lórí ilé OLÚWA náà. Fiyèsí ẹnu ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́.