Ezekiel 44:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ẹ̀ ń gbà fún àwọn àlejò, tí a kò kọ nílà abẹ́, ati ti ọkàn, láti máa wọ ibi mímọ́ mi nígbà tí ẹ bá ń fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi, ibi mímọ́ mi ni ẹ̀ ń sọ di aláìmọ́. Ẹ ti fi àwọn ohun ìríra yín ba majẹmu mi jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Niti pe ẹ mu ọmọ-ajèji, alaikọla aiya, ati alaikọla ara wa, lati wà ni ibi-mimọ́ mi, lati sọ ọ di alailọ̀wọ, ani ile mi, nigbati ẹ rú akara mi, ọ̀ra ati ẹjẹ, nwọn si bà majẹmu mi jẹ nipa gbogbo ohun-irira nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àfikún pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà ìríra rẹ tí ó kù, ìwọ mú àwọn àjòjì aláìkọlà àyà àti ara wá sí inú ibi mímọ́ mi, ní lílo ilé mi ní ìlòkúlò nígbà tí ìwọ fi oúnjẹ fún mi, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ìwọ sì ba májẹ̀mú mi jẹ́.