Ezekiel 44:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“ ‘Nítorí náà, ẹni tí kò bá kọlà ọkàn ati ti ara ninu àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Gbogbo ọmọ àjeji, alaikọla aiya, tabi alaikọla ara kì yio wọ̀ inu ibi mimọ́ mi, ninu gbogbo ọmọ àjeji ti o wà lãrin awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí yìí ní OLÚWA Ọba wí: Àjòjì aláìkọlà àyà àti ara kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi, àti pẹ̀lú àwọn àjòjì tí ń gbé ní àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.