Ezekiel 45:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan, ẹ ya ilẹ̀ kan sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí yóo jẹ́ ilẹ̀ mímọ́. Gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ. Ilẹ̀ mímọ́ ni gbogbo ilẹ̀ náà yóo jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
PẸLUPẸLU nigbati ẹnyin ba fi ibo pín ilẹ li ogún, ẹ o gbé ọrẹ wá fun Oluwa, eyiti o mọ́ lati ilẹ na wá: gigùn na yio jẹ ẹgbã le ẹgbẹrun ije ni gigùn, ati ẹgbãrun ni ibú. Eyi yio jẹ́ mimọ́ ni gbogbo àgbegbe rẹ̀ yika.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí agbègbè mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀; gbogbo agbègbè náà ni yóò jẹ́ mímọ́.