Ezekiel 45:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ níláti ya aguntan kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ ninu agbo ẹran kọ̀ọ̀kan tí ó tó igba ẹran, ninu àwọn agbo ẹran ìdílé Israẹli. Ẹ yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, kí wọ́n lè ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọdọ-agutan kan lati inu agbo, lati inu igba, lati inu pápa tutù Israeli; fun ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati fun ọrẹ ẹbọ sisun, fun ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati fi ṣe ètutu fun wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bákan náà ni àwa yóò mú àgùntàn kan láti inú agbo ẹran tí ó jẹ́ igba láti inú kanga omi pápá oko tútù tí Ísírẹ́lì. Ìwọ̀nyí ni wọn yóò lò fún àwọn ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ẹbọ sísun àti ìdàpọ̀ ọrẹ ẹbọ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní OLÚWA Ọba sọ.