Ezekiel 45:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba ni ó gbọdọ̀ máa pèsè ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún, ati àwọn ọjọ́ oṣù tuntun, àwọn ọjọ́ ìsinmi ati àwọn ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Òun ni yóo máa pèsè ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti ọmọ-alade yio jẹ́ ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ mimu, ninu asè gbogbo, ati ni oṣù titun, ati ni awọn ọjọ isimi, ni gbogbo ajọ ile Israeli: on o pèse ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati ṣe etùtu fun ile Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àṣè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ ìsìnmi ni gbogbo àjọ ilé Ísírẹ́lì. Oun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Ísírẹ́lì.